ILARO ANTHEM.

(As Composed by The Late Senator (Professor) Afolabi OLABIMTAN).

Ilu ARO Idere,
Amujemuta, Ilu Aro;
Iwo t’o f’oke s’aso bora,
Mo ki e, ki e, Ilu mi!
Om’ ORONNA, On’ile iki
T’o f’aireni baja, t’o ja’gboro l’ogun
Mo ki e, ki e, Ilu mi!
Omo Asabo, Iya Ala (2ce)
Asabo Okege, Odoyimika
Ilu mi, mo ki e, ki e.
Asabo Oo, Mo ki e, ki e, Ilu mi.
Oduduwa, Mo’ p’Agbeji
Mo pe Onile Ejimaki
Mo pe Orunpeku Oke
Mo ki e, ki e, Ilu mi.
Ma f’ori sise, ma f’orun se
Fun Ilu Aro, Ilu mi.
Ki n le mu u g’oke Agba,
Fun ‘losiwaju gbogbo wa!
Om’Oronna, Ee je k’a jo
Omo Asabo, e je k’a yo
E je k’a pa’mopo sokan
K’a sise sise fun Ilu wa (3ce)
Fun ‘losiwaju gbogbo wa Ogbo!

About Idowu Hamed

Publisher and Editor in Chief - Magazine and Online Email: startrendinter@gmail.com